11. Nítorí nípasẹ̀ mi ọjọ́ rẹ yóò gùnọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún yóò sì kún ọjọ́ ayé rẹ.
12. Bí ìwọ bá gbọ́n, ọgbọ́n rẹ yóò fún ọ ní èrè:bí ìwọ bá jẹ́ ẹlẹ́gàn, ìwọ nìkan ni yóò jìyà.”
13. Òmùgọ̀ obìnrin jẹ́ aláriwo;ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláì ní ìmọ̀.
14. Ó jókòó lẹ́nu ọ̀nà ilé rẹ̀lórí ìjòkó níbi tí ó ga jù láàrin ìlú,
15. ó ń pe àwọn tí ó ń kọjá lọ,tí wọn ń lọ tààrà ní ọ̀nà wọn.
16. “Jẹ́ kí gbogbo ẹni tí ó jẹ́ aláìlóye súnmọ́ bí!”Ni ó wí fún ẹni tí òye kù díẹ̀ ká à tó fún.
17. “Omi tí a jí mu dùnoúnjẹ tí a jẹ ní ìkọ̀kọ̀ a máa ládùn!”
18. Ṣùgbọ́n wọn ò funra pé àwọn òkú wà níbẹ̀,pé àwọn àlejò rẹ̀ wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ isà òkú.