Òwe 3:13-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀,ẹni tí ó tún ní òye síi

14. Nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọó sì ní èrè lórí ju wúrà lọ.

15. Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ;kò sí ohunkohun tí a lè fi wé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́.

16. Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀;ní ọwọ́ òsì rẹ̀ sì ni ọrọ̀ àti ọlá.

17. Àwọn ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà ìtura,òpópónà rẹ̀ sì jẹ́ ti àlàáfíà.

18. Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbàá;àwọn tí ó bá sì dìí mú yóò rí ìbùkún gbà.

19. Nípa ọgbọ́n, Olúwa fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀; nípa òye, ó fi àwọn ọ̀run sí ipòo wọn;

20. Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ó pín ibú omi ní ìyà,àwọ̀sánmọ̀ sì ń sẹ ìrì.

21. Ọmọ mi pa ìdájọ́ tí ó yè kooro mọ́ àti ìmọ̀yàtọ̀,má jẹ́ kí wọn lọ kúrò ní ibi tí ojú rẹ ti le tó wọn

22. wọn yóò jẹ́ ìyè fún ọàti ẹ̀ṣọ́ fún ọrùn rẹ

23. Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọ̀nà rẹ lọ ní àìṣéwu,ìwọ kì yóò sì kọsẹ̀;

24. Nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, ìwọ kì yóò bẹ̀rùnígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, oorun rẹ yóò jẹ́ oorun ayọ̀

25. má ṣe bẹ̀rù ìdàámú òjijìtàbí ti ìparun tí ó ń dé bá àwọn ènìyàn búburú

26. Nítorí Olúwa yóò jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹkì yóò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ bọ́ sínú pàkúté.

27. Má ṣe fa ọwọ́ ire sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ó tọ́ sí,nígbà tí ó bá wà ní ìkápá rẹ láti ṣe ohun kan.

Òwe 3