2. Ìṣúra tí a kójọ nípa ìwà búburú kò ní èrèṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú.
3. Olúwa kì í jẹ́ kí ebi máa pa Olódodoṣùgbọ́n ó ba ète àwọn ènìyàn búburú jẹ́.
4. Ọwọ́ tí ó lẹ máa ń sọ ènìyàn di talákà,ṣùgbọ́n ọwọ́ tí ó múra síṣẹ́ a máa sọni di ọlọ́rọ̀.
5. Ẹni tí ó kó irúgbìn jọ ní àsìkò òjò jẹ́ Ọlọ́gbọ́n ọmọ,ṣùgbọ́n ẹni tí ó sùn ní àsìkò ìkórè jẹ́ adójútini ọmọ.
6. Ìbùkún ní ó máa ń kún orí Olódodoṣùgbọ́n ìwà ipá máa ń kún ẹnu ènìyàn búburú.
7. Ìrántí Olódodo yóò jẹ́ ìbùkúnṣùgbọ́n orúkọ ènìyàn búburú yóò jẹrà.
8. Ẹni tí ó gbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ máa ń gba àṣẹṣùgbọ́n ètè wérewère yóò parun.