8. Kí a lọ kúrò ní Lẹ́bánónì, ìyàwó mi,ki a lọ kúrò ní Lẹ́bánónì.Àwa wò láti orí òkè Ámánà,láti orí òkè ti Ṣénírì, àti téńté Hérímónì,láti ibi ihò àwọn kìnnìún,láti orí òkè ńlá àwọn ẹkùn.
9. Ìwọ ti gba ọkàn mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi;Ìwọ ti gba ọkàn mipẹ̀lú ìwò ẹ̀ẹ̀kan ojú rẹ,pẹ̀lú ọ̀kan nínú ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ,
10. Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó, arábìnrin mi, ìyàwó mi!Ìfẹ́ rẹ tu ni lára ju ọtí wáìnì lọ,òórùn ìkunra rẹ sì ju òórùn gbogbo tùràrí lọ!
11. Ètè rẹ ń kán dídùn afárá oyin, ìyàwó mi;wàrà àti oyin wà lábẹ́ ahọ́n rẹ.Òórùn aṣọ rẹ sì dàbí òórùn Lébánónì.
12. Arábìnrin mi ni ọgbà tí a sọ, arábinrin mi, ìyàwó miìṣun tí a sé mọ́, oríṣun tí a fi èdìdì dì.