Nọ́ḿbà 26:43-55 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

43. Gbogbo ìdílé àwọn ọmọ Ṣúhámù, gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàáméjìlélọ́gbọ̀n ó lé irínwó (64,400).

44. Ti àwọn ọmọ Ásérì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:ti Ímínà, ìdílé àwọn ọmọ Ímínà;ti Íṣífì, ìdílé àwọn ọmọ Íṣífì;ti Béríà, ìdílé àwọn ọmọ Béríà;

45. Ti àwọn ọmọ Béríà:ti Hébérì, ìdílé àwọn ọmọ Hébérì;ti Mákíẹ́lì, ìdílé àwọn ọmọ Mákíẹ́lì.

46. (Orúkọ ọmọ Áṣérì obìnrin nì jẹ́ Ṣérà.)

47. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Áṣérì gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé egbéje (53,400).

48. Ti àwọn ọmọ Náfítalì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:ti Jásélì, ìdílé àwọn ọmọ Jásélì:ti Gúnì, ìdílé àwọn ọmọ Gúnì;

49. ti Jésérì, ìdílé àwọn ọmọ Jéṣérì;ti Ṣílémù, ìdílé àwọn ọmọ Ṣilemù.

50. Wọ̀nyí ni ìdílé ti Náfítalì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé egbéje (45,400).

51. Àpapọ̀ iye tí a kà nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́, ó lé ẹgbẹ̀sán ó dín àádọ́rin (601,730).

52. Olúwa sọ fún Mósè pé,

53. “Ilẹ̀ náà gbọdọ̀ jẹ́ pínpín fún wọn gẹ́gẹ́ bí ogún wọn gẹ́gẹ́ bí iye orúkọ wọn

54. Fún àwọn ọ̀pọ̀ ni kí ìwọ ó fún ní ogún ìlú púpọ̀ àti fún àwọn tí ó kéré ni kí ìwọ ó fi kékeré fún, ẹnìkọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ gba ogún ìbí tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí a kọ.

55. Rí dájú pé ilẹ̀ yìí gbọdọ̀ jẹ́ fífi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọn sì ti pọ̀ tó. Gẹ́gẹ́ bí orúkọ ẹ̀yà àwọn baba wọn ni kí wọn kí ó ni ín.

Nọ́ḿbà 26