4. Nígbà tí àwọn ènìyàn tó kù nínú àwọn Júdà àti Bẹ́ńjámínìn ń gbé ní Jérúsálẹ́mù):Nínú àwọn ọmọ Júdà:Átaáyà ọmọ Úṣáyà ọmọ Ṣekaráyà, ọmọ Ámáráyà, ọmọ Ṣefatayà, ọmọ Máhálálélì, ìran Pérésì;
5. àti Maaṣeayà ọmọ Bárúkì, ọmọ Koli-Hóṣè, ọmọ Haṣaíyà, ọmọ Ádáyà, ọmọ Joiaribù, ọmọ Ṣekaráyà, ìran Ṣélà.
6. Àwọn ìran Pérésì tó gbé ní Jérúsálẹ́mù jẹ́ àádọ́rin lé nírínwó ó dín méjì (468) alágbára ọkùnrin.
7. Nínú àwọn ìran Bẹ́ńjámínì:Ṣálù ọmọ Mésúlámù, ọmọ Jóédì, ọmọ Pédáyà, ọmọ Kóláyà, ọmọ Maaṣéyà, ọmọ Itíélì, ọmọ Jéṣáyà,
8. àti àwọn ọmọ ẹ̀yìnin rẹ̀, Gábáì àti Ṣáláì jẹ́ ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rún ó lé mẹ́jọ (928) ọkùnrin.
9. Jóẹ́lì ọmọ Ṣíkírì ni olóórí òṣìṣẹ́ ẹ wọn, Júdà ọmọ Haṣenuáyà sì ni olórí agbégbé kejì ní ìlú náà.
10. Nínú àwọn àlùfáà:Jédáyà; ọmọ Jóáríbù; Jákínì;
11. Ṣéráyà ọmọ Hílíkáyà, ọmọ Mésúlámù, ọmọ Ṣádókì, ọmọ Méráótì, ọmọ Áhítúbì alábojútó ní ilé Ọlọ́run,
12. àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, ẹni tí ó ń ṣe iṣẹ́ ní tẹ́ḿpìlì jẹ́ ẹgbẹ̀rin ó lé mẹ́rinlélógún (822) ọkùnrin: Ádáyà ọmọ Jéróhámù, ọmọ Péláyà, ọmọ Ámísì, ọmọ Ṣakaráyà, ọmọ Pásúrì, ọmọ Málíkíjà,
13. àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olórí ìdílé jẹ́ òjìlúgba ó lé méjì (242) ọkùnrin: Ámáṣíṣáì ọmọ Áṣárélì, ọmọ Áṣáì, ọmọ Méṣílémótì, ọmọ Ìmérì,
14. àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ alágbára ọkúnrin jẹ́ méjìdínláàdọ́je (128). Olórí òṣìṣẹ́ ẹ wọn ni Sábídíelì ọmọ Hágédólímù.