Lúùkù 4:22-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Gbogbo wọn sì jẹ́rìí rẹ̀, háà sì ṣe wọ́n sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ń jáde ní ẹnu rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Ọmọ Jósẹ́fù kọ́ yìí?”

23. Jésù sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni ẹ̀yin ó pa òwé yìí sí mi pé, ‘Oníṣègùn, wo ara rẹ̀ sàn! Àwọn ohun tí àwá gbọ́ pé o ti ọwọ́ rẹ ṣe ní Kapanáúmù, ṣe é níhín yìí pẹ̀lú ní ilẹ̀ ara rẹ.’ ”

24. Ó sì wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, kò sí wòlíì tí a tẹ́wọ́ gbà ní ilẹ̀ baba rẹ̀.

25. Ṣùgbọ́n mo wí fún un yín nítòótọ́, opó pípọ̀ ni ó wà ní Ísírẹ́lì nígbà tí ọ̀run fi sé ní ọdún mẹ́ta òun oṣù mẹ́fà, nígbà tí ìyàn ńlá fi mú ká ilẹ̀ gbogbo;

26. Kò sì sí ẹnìkan nínú wọn tí a rán Èlíjà sí, bí kò ṣe sí obìnrin opó kan ní Sáréfátì, ìlú kan ní Ṣídónì.

27. Adẹ́tẹ̀ púpọ̀ ní sì ń bẹ ní Ísírẹ́lì nígbà wòlíì Èlíṣà; kò sì sí ọ̀kan nínú wọn tí a wẹ̀nùmọ́, bí kò ṣe Námánì ará Síríà.”

28. Nígbà tí gbogbo àwọn tí ó wà nínú sínágọ́gù gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, inú wọ́n ru ṣùṣù,

29. Wọ́n sì dìde, wọ́n tì í sóde sí ẹ̀yìn ìlú, wọ́n sì fà á lọ sí bèbè òkè níbi tí wọ́n gbé tẹ ìlú wọn dó, kí wọn bá à lè taari rẹ̀ ní ògèdèǹgbé.

30. Ṣùgbọ́n ó kọjá láàrin wọn, ó bá tirẹ̀ lọ.

31. Ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Kápánáúmù, ìlú kan ní Gálílì, ó sì ń kọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi.

Lúùkù 4