Lúùkù 21:8-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ó sì wí pé, “Ẹ máa kíyèsára, kí a má báà mú yín sìnà: nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò wá ní orúkọ mi, tí yóò máa wí pé, ‘Èmi ní Kírísítì náà àkókò náà sì kù sí dẹ̀dẹ̀.’ Ẹ má ṣe tọ̀ wọ́n lẹ́yìn.

9. Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá gbúròó ogun àti ìdágìrì, ẹ má ṣe fòyà; nítorí nǹkan wọ̀nyí ní láti kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀: ṣùgbọ́n òpin náà kì í ṣe lójúkan náà.”

10. Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba.

11. Ilẹ̀ríri ilẹ̀ ńlá yóò sì wà káàkiri, àti ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn; ohun ẹ̀rù, àti àmì ńlá yóò sì ti ọ̀run wá.

12. “Ṣùgbọ́n ṣáájú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọn ó nawọ́ mú yín, wọn ó sì ṣe inúnibíni sí yín, wọn ó mú yín lọ sí sínágọ́gù, àti sínú túbú, wọn ó mú yín lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba àti àwọn ìjòyè nítorí orúkọ mi.

13. Yóò sì padà di ẹ̀rí fún yín.

14. Nítorí náà ẹ pinnu rẹ̀ lọ́kàn yín pé ẹ yóò ronú ṣáájú, bí ẹ ó ti dáhùn.

15. Nítorí tí èmi ó fún yín ní ẹnu àti ọgbọ́n, tí gbogbo àwọn ọ̀tá yín kì yóò lè sọ̀rọ̀-òdì sí, tí wọn kì yóò sì lè kò lójú.

16. A ó sì fi yín hàn láti ọwọ́ àwọn òbí yín wá, àti àwọn arákùnrin, àti àwọn ìbátan, àti àwọn ọ̀ré; on ó sì mú kì a pa nínú yín.

17. A ó sì kórìíra yín lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí orúkọ mi.

18. Ṣùgbọ́n irun orí yín kan kì yóò ṣègbé.

19. Nínú sùúrù yín ni ẹ̀yin ó jèrè ọkàn yín.

20. “Nígbà tí ẹ̀yin bá sì rí ti a fi ogun yí Jerúsálémù ká, ẹ mọ̀ nígbà náà pé, ìsọdahoro rẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀.

21. Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdéà sá lọ sórí òkè; àti àwọn tí ń bẹ láàrin rẹ̀ kí wọn jáde kúrò; kí àwọn tí ó sì ń bọ̀ ní ìgbéríko má ṣe wọ inú rẹ̀ wá.

22. Nítorí ọjọ́ ẹ̀san ni ọjọ́ wọ̀nyí, kì a lè mú ohun gbogbo tí a ti kọ̀wé rẹ̀ ṣẹ.

23. Ṣùgbọ́n ègbé ni fún àwọn tí ó lóyún, àti àwọn tí ó fí ọmú fún ọmọ mu ní ijọ́ wọ̀nyí! Nítorí tí ìpọ́njú púpọ̀ yóò wà lórí ilẹ̀ àti ìbínú sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí.

24. Wọn ó sì ti ojú idà ṣubú, a ó sì dì wọ́n ní ìgbékùn lọ sí orílẹ̀-èdè gbogbo; Jerúsálémù yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aláìkọlà, títí àkókò àwọn aláìkọlà yóò fi kún.

25. “Àmì yóò sì wà ní ọ̀run, àti ní òṣùpá, àti ní ìràwọ̀; àti lórí ilẹ̀ ayé ìdààmú fún àwọn orílẹ̀-èdè nínú ìpáyà híhó òkun àti ìgbì-omi.

Lúùkù 21