Lúùkù 2:18-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ sí nǹkan wọ̀nyí tí a ti wí fún wọn láti ọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́-àgùntàn wá.

19. Ṣùgbọ́n Màríà pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́, ó ń rò wọ́n nínú ọkàn rẹ̀.

20. Àwọn olùṣọ́-àgùntàn sì padà lọ, wọ́n ń fi ògo fún Ọlọ́run, wọ́n sì yìn ín, nítorí ohun gbogbo tí wọ́n ti gbọ́ àti tí wọ́n ti rí, bí a ti wí i fún wọn.

21. Nígbà tí ijọ́ mẹ́jọ sì pé láti kọ ọmọ náà nílà, wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù, bí a ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ańgẹ́lì náà wá kí á tó lóyún rẹ̀ nínú.

22. Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nù Màríà sì pé gẹ́gẹ́ bí òfin Mósè, Josefu àti Màríà gbé Jésù wá sí Jerúsálémù láti fi í fún Olúwa;

23. (Bí a ti kọ ọ́ sínú òfin Olúwa pé, “Gbogbo ọmọ ọkùnrin tí ó ṣe àkọ́bí, òun ni a ó pè ní mímọ́ fún Olúwa”),

24. àti láti rúbọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí a wí nínú òfin Olúwa: “àdàbà méjì tàbí ẹyẹlẹ́ méjì.”

25. Sì kíyèsí i, ọkùnrin kan wà ní Jerúsálémù, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Ṣíméónì; ọkùnrin náà sì ṣe olóòótọ́ àti olùfọkànsìn, ó ń retí ìtùnú Ísírẹ́lì: Ẹ̀mí mímọ́ sì bà lé e.

26. A sì ti fihàn án láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ náà wá pé, òun kì yóò rí ikú, kí ó tó rí kírísítì Olúwa.

27. Ó sì ti ipa Ẹ̀mí wá sínú tẹ́ḿpìlì: nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ sì gbé ọmọ náà Jésù wá, láti ṣe fún un bí ìṣe òfin,

28. Nígbà náà ni Símọ́nì gbé e ní apá rẹ̀, ó fi ìbùkún fún Ọlọ́run, ó ní:

29. “Olúwa alágbára, nígbàyí ni o tó jọ̀wọ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ lọ́wọ́ lọ,Ní àlààáfíà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ rẹ:

30. Nítorí tí ojú mi ti rí ìgbàlà rẹ ná,

31. Tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀ níwájú ènìyàn gbogbo;

32. Ìmọ́lẹ̀ láti mọ́ sí àwọn aláìkọlà,Àti ògo Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ̀.”

33. Ẹnu sì ya Jóṣéfù àti ìyá rẹ̀ sí nǹkan tí a ń sọ sí i wọ̀nyí.

34. Síméónì sì súre fún wọn, ó sì wí fún Màríà ìyá rẹ̀ pé: “Kíyèsí i, a gbé ọmọ yìí kalẹ̀ fún ìṣubú àti ìdìde ọ̀pọ̀ ènìyàn ní Ísírẹ́lì; àti fún àmì tí a ń sọ̀rọ̀ òdì sí;

35. (Idà yóò sì gún ìwọ náà ní ọkàn pẹ̀lú) kí á lè fi ìrònú ọ̀pọ̀ ọkàn hàn.”

36. Ẹnìkan sì ń bẹ, Ánà wòlíì, ọmọbìnrin Fánúénì, ní ẹ̀yà Ásérì: ọjọ́ ogbó rẹ̀ pọ̀, ó ti bá ọkọ gbé ní ọdún méje láti ìgbà wúndíá rẹ̀ wá;

37. Ó sì ṣe opó títí ó fi di ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin, ẹni tí kò kúrò ní tẹ́ḿpílì, ṣùgbọ́n ó ń fi àwẹ̀ àti àdúrà sin Ọlọ́run lọ́sàn-án àti lóru.

Lúùkù 2