1. Ó sì ṣe ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àṣẹ ti ọ̀dọ̀ Késárì Ògọ́sítù jáde wá pé, kí a kọ orúkọ gbogbo ìjọba Rosínú ìwé.
2. (Èyí ni ìkọ sínú ìwé ìkínní tí a ṣe nígbà tí Kíréníyù fi jẹ Baálẹ̀ Síríà.)
3. Gbogbo àwọn ènìyàn sì lọ láti kọ orúkọ rẹ̀ sínú ìwé, olúkúlùkù sí ìlú ara rẹ̀.
4. Jóṣéfù pẹ̀lú sì gòkè láti Násárẹ́tì ìlú Gálílì, sí ìlú Dáfídì ní Jùdéà, tí à ń pè ní Bétílẹ́hẹ́mù; nítorí ti ìran àti ìdílé Dáfídì ní í ṣe,
5. Láti kọ orúkọ rẹ̀, pẹ̀lú Màríà aya rẹ̀ àfẹ́sọ́nà, tí oyún rẹ̀ tí tó bi.
6. Ó sì ṣe, nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, ọjọ́ rẹ̀ pé tí òun óò bí.
7. Ó sì bí àkọ́bí rẹ̀ ọmọkùnrin, ó sì fi ọ̀já wé e, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran; nítorí tí àyè kò sí fún wọn nínú ilé èrò.
8. Àwọn olùsọ́-àgùntàn ńbẹ tí wọ́n ń gbé ní ìlú náà, wọ́n ń sọ́ agbo àgùntàn wọn ní òru ní pápá tí wọ́n ń gbé.
9. Ańgẹ́lì Olúwa sì yọ sí wọn, ògo Olúwa sì ràn yí wọn ká: ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi.
10. Ańgẹ́lì náà sì wí fún wọn pé, Má bẹ̀rù: sá wò ó, mo mú ìyìn rere ayọ̀ ńlá fún yín wá, tí yóò ṣe ti ènìyàn gbogbo.
11. Nítorí a ti bí Olùgbàlà fún yín lónì-ín ní ìlú Dáfídì, tí í ṣe Kírísítì Olúwa.