Lúùkù 19:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Jésù sì wọ Jẹ́ríkò lọ, ó sì ń kọjá láàrin rẹ̀.

2. Sì kíyèsí i, ọkùnrin kan wà tí a ń pè ní Sákéù, ó sì jẹ́ olórí agbowó òde kan, ó sì jẹ́ ọlọ́rọ̀.

3. Ó sì ń fẹ́ láti rí ẹni tí Jésù jẹ́: kò sì lè rí i, nítrorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, àti nítorí tí òun jẹ́ ènìyàn kúkúrú.

4. Ó sì súré ṣíwájú, ó gun orí igi síkámórè kan, kí ó bà lè rí i: nítorí tí yóò kọjá lọ níhà ibẹ̀.

Lúùkù 19