Lúùkù 1:28-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Ańgẹ́lì náà sì tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Àlààáfíà, ìwọ ẹni tí a kọjú sí ṣe ní oore, Olúwa ńbẹ pẹ̀lú rẹ”

29. Ṣùgbọ́n ọkàn Màríà kò lélẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ náà, ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, irú kíkí kínni èyí.

30. Ṣùgbọ́n àńgẹ́lì náà wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, Màríà: nítorí ìwọ ti rí ojúrere lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

31. Ìwọ óò lóyún nínú rẹ, ìwọ ó sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní JÉSÙ.

32. Òun ó pọ̀, Ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó sì máa pè é: Olúwa Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀ fún:

Lúùkù 1