Júdà 1:6-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Àti àwọn ańgẹ́lì tí kò tọ́jú ipò ọlá wọn, ṣùgbọ́n tí wọn fi ipò wọn sílẹ̀, àwọn tí ó pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n àìnípẹ̀kun ní ìṣàlẹ̀ òkùnkùn de ìdájọ ọjọ́ ńlá nì.

7. Àní bí Sódómù àti Gomorà, àti àwọn ìlú agbégbé wọn, ti fi ara wọn fún àgbérè ṣíṣe, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé ará àjèjì lẹ́yìn, àwọn ni ó fi lélẹ̀ bí àpẹrẹ, àwọn tí ó ń jìyà iná àìnípẹ̀kun.

8. Bákan náà ni àwọn wọ̀nyí ń sọ ara wọn di èérí nínú àlá wọn, wọ́n ń gan ìjoye, wọn sì ń sọ̀rọ̀ búbúrú sí àwọn ọlọ́lá.

9. Ṣùgbọ́n Mákẹ́lì, olórí awọn ańgẹ́lì, nígbà tí ó ń bá Èṣù jiyàn nítórí òkú Mósè, kò sọ ọ̀rọ̀ òdì sí i; Ṣùgbọ́n ó wí pé, “Olúwa bá ọ wí.”

10. Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí n sọ̀rọ̀ òdì sí ohun gbogbo ti kò yé wọn: ṣùgbọ́n ohun gbogbo tí wọn mọ̀ nípa ìròfún-ara, bí ẹranko tí kò ní ìyè, nípaṣẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n di ẹni ìparun.

11. Ègbé ni fún wọn! Nítorí tí wọ́n ti rìn ní ọ̀nà Káínì, wọ́n sì fi ìwọra súré sínú ìsìnà Bálámù nítorí ère, wọn ṣègbé nínú ìṣọ̀tẹ̀ Kórà.

12. Àwọn wọ̀nyí ní ó jẹ́ àbàwọ́n nínú àṣè ìfẹ́ yín, nígbà tí wọ́n ń bá yín jẹ àsè, àwọn olùsọ́ àgùntàn ti ń bọ́ ara wọn láìbẹ̀rù. Wọ́n jẹ́ ìkùùkuu láìrọ òjò, tí a ń ti ọwọ́ afẹ́fẹ́ gbá kiri; àwọn igi aláìléso ní àkókò èso, wọ́n kú lẹ́ẹ̀méjì, a sì fà wọn tú ti-gbòǹgbò-ti-gbòǹgbò.

13. Wọ́n jẹ́ ìjì líle ti ń ru ní ojú omi òkun, ti ń hó ìfófó ìtìjú wọn jáde; alárìnkiri ìràwọ̀, àwọn tí a pa òkùnkùn biribiri mọ́ dè láéláé.

14. Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ni Énọ́kù, ẹni keje láti ọ̀dọ̀ Ádámù, sọ̀tẹ́lẹ̀ nípa wọn pé “Kíyèsí i, Olúwa ń bọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn rẹ̀ mímọ́,

15. láti ṣe ìdájọ́ gbogbo ènìyàn, láti dá gbogbo àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run lẹ́bi ní ti gbogbo iṣẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run wọn, ti wọ́n ti fi àìwà-bí-Ọlọ́run ṣe, àti ní ti gbogbo ọ̀rọ̀ líle tí àwọn ẹlẹ́sẹ̀ aláìwà-bí-Ọlọ́run ti sọ sí i.”

16. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní àwọn ti ń kùn, àwọn aláròyé, ti ń rìn nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn; wọn ń gbéraga nipa ara wọn, wọ́n sì ń ṣáta àwọn ènìyàn mìíràn fún èrè ara wọn.

17. Ṣùgbọ́n ẹyin olùfẹ́, ẹ rántí àwọn ọ̀rọ tí a ti sọ ṣááju láti ọwọ́ àwọn Àpósítélì Olúwa wa Jésù Kírísítì.

18. Bí wọn ti wí fún yín pé, “Nígbà ìkẹyìn àwọn ẹlẹ́gàn yóò wà, tí wọn yóò máa rìn gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run ti ara wọn.”

19. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni àwọn ẹni tí ń ya ara wọn sí ọ̀tọ̀, àwọn ẹni tí ara, tí wọn kò ni Ẹ̀mí.

20. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, olùfẹ́, ti ẹ ń gbé ara yín ró lórí ìgbàgbọ́ yín tí ó mọ́ jùlọ, ti ẹ ń gbàdúrà nínú Ẹ̀mí Mímọ́.

Júdà 1