4. Àti agbégbé Ógù ọba Básánì,ọ̀kan nínú àwọn tí ó kù nínú àwọn ará Ráfíátì, ẹni tí ó jọba ní Ásítarótù àti Édírì.
5. Ó se àkóso ní orí Okè Hámónì, Sálékà, Básánì títí dé ààlà àwọn ènìyàn Gésúrì àti Máákà, àti ìdajì Gílíádì dé ààlà Síhónì ọba Hésíbónì.
6. Mósè ìránṣẹ́ Olúwa àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì borí wọn. Mósè ìránṣẹ́ Olúwa sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Rúbẹ́nì, àwọn ẹ̀yà Gádì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè kí ó jẹ́ ohun ìní wọn.
7. Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí Jóṣúà àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sẹ́gun ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Jọ́dánì, láti Báálì Gádì ní Àfonífojì Lẹ́bánónì sí Okè Hálákì, èyí tí O lọ sí ọ̀nà Sérì (Jóṣúà sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ ìní gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn: