19. Bí èmi bá rí olùpọ́njú láìní aṣọ,tàbí talákà kan láìní ìbora;
20. Bí ọkàn rẹ̀ kò bá súre fún mi,tàbí bí ara rẹ̀ kò sì gbóná nípaṣẹ̀ irun àgùntàn mi;
21. Bí mo bá sì gbé ọwọ́ mi sókè síaláìní baba, nítorí pé mo rí ìrànlọ́wọ́ mi ní ẹnu ibodè,
22. Ǹjẹ́, ní apá mi kí o wọ́n kúrò níọkọ́ èjìká rẹ̀, kí apá mi kí ó sì ṣẹ́ láti egungun rẹ̀ wá.
23. Nítorí pé ìparun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́runwá ni ẹ̀rù-ńlá fún mi, àti nitorí Ọláńlá rẹ̀ èmi kò le è dúró.
24. “Bí ó bá ṣe pé mo fi wúrà ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé mi,tàbí tí mo bá wí fún fàdákà dídára pé, ‘Ìwọ ni ààbò mi;’