Jóòbù 10:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Agara ìwà ayé mi dá mi tán,èmi yóò tú àròyé mi sókè lọ́dọ̀ mi,èmi yóò máa sọ níní kíkorò ìbìnújẹ́ ọkàn mi.

2. Èmi yóò wí fún Ọlọ́run pé: má ṣe dámi lẹ́bi;fi hàn mí nítorí ìdí ohun tí ìwọ fí ń bá mi jà.

3. Ó ha tọ́ tí ìwọ ì bá fi máa ni mílára, tí ìwọ ìbá fi máa gan iṣẹ́ọwọ́ rẹ tí ìwọ yóò fi máa tànìmọ́lẹ̀ sí ìmọ̀ ènìyàn búrurú.

4. Ojú rẹ ìha ṣe ojú ènìyàn bí?Tàbí ìwọ a máa ríran bí ènìyàn ti í ríran?

5. Ọjọ́ rẹ ha dàbí ọjọ́ ènìyàn,ọdún rẹ ha dàbí ọjọ́ ènìyàn?

6. Tí ìwọ fi ń bèèrè àìṣedédé mi,tí ìwọ sì fi wá ẹ̀ṣẹ̀ mi rí?

7. Ìwọ mọ̀ pé èmi kì í ṣe oníwà búburú,kò sì sí ẹni tí ó le gbà mí kúrò ní ọwọ́ rẹ?

8. “Ọwọ́ rẹ ni ó dámi,tí ó sì mọ mí pọ̀ yíkákiri;síbẹ̀ ìwọ sì ńbà mí jẹ́.

9. Èmi bẹ̀ ọ́ rántí pé ìwọ tí ìwọ timọ mí bí amọ̀; ìwọ yóò ha sìtún mú mi lọ padà sí erùpẹ̀?

10. Ìwọ kò ha ti tún mí dà jáde bí i wàrà,ìwọ kò sì múmí dípò bí i wàràǹkàsì?

11. Ìwọ sá ti fi àwọ̀ ẹran ara wọ̀ mí,ìwọ sì fi egungun àti iṣan ṣọgbà yí mi ká.

12. Ìwọ ti fún mi ní ẹ̀mí àti ojú rere,ìbẹ̀wò rẹ sì pa ọkàn mi mọ́.

Jóòbù 10