Jòhánù 12:11-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Nítòrí pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù jáde lọ, wọ́n sì gbà Jésù gbọ́.

12. Ní ijọ kejì nígbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó wá sí àjọ gbọ́ pé, Jésù ń bọ̀ wá sí Jérúsálẹ́mù.

13. Wọ́n mú imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n sì jáde lọ pàdé rẹ̀, wọ́n sì ń kígbe pé,“Hòsánnà!”“Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀wá ní orúkọ Olúwa, ọba Ísríẹ́lì!”

14. Nígbà tí Jésù sì rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, ógùn ún; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé pé,

15. “Má bẹ̀rù, ọmọbìnrin Síónì;Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá,Ó jókòó lórí ọmọ kẹ́tẹ́ktẹ́.”

16. Nǹkan wọ̀nyí kò tètè yé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀: ṣùgbọ́n nígbà tí a ṣe Jésù lógo, nígbà náà ni wọ́n rántí pé, a kọ̀wé ǹkan wọ̀nyí nípa rẹ̀ sí i.

17. Nítorí náà, ìjọ ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Lásárù jáde nínú ibojì rẹ̀, tí ó sì jí i dìde kúrò nínú òkú, jẹ́rí sí i.

18. Nítorí èyí ni ìjọ ènìyàn sì ṣe lọ pàdé rẹ̀, nítorí tí wọ́n gbọ́ pé ó ti ṣe iṣẹ́ àmì yìí.

19. Nítorí náà àwọn Farisí wí fún ara wọn pé, “Ẹ kíyèsi bí ẹ kò ti lè borí ní ohunkóhun? Ẹ wo bí gbogbo ayé ti ń wọ́ tọ̀ ọ́!”

Jòhánù 12