23. Pomegiranátì mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún ni ó wà ní àwọn ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àpapọ̀ gbogbo pomegiranátì sì jẹ́ ọgọ́rùn ún kan.
24. Balógun àwọn ẹ̀sọ́ mu Ṣeráyà olórí àwọn àlùfáà àti Ṣefanáyà tí ó jẹ́ igbá kejì rẹ̀ àti gbogbo àwọn asọ́nà.
25. Nínú àwọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà, ó mú alásẹ tí ó wà ní ìtọ́jú àwọn ológun, àti àwọn olùdámọ̀ràn Ọba méje. Bákan náà, ó tún mu akọ̀wé olórí ogun tí ó wà ní ìtọ́jú títo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti ọgọ́ta nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n rí ní ìlú náà.
26. Nebusaradánì balógun náà kó gbogbo wọn, ó sì mú wọn lọ sọ́dọ̀ Ọba Bábílónì ní Ríbílà.
27. Ní Ríbílà ni ilẹ̀ Hámátì Ọba náà sì pa wọ́n. Báyìí ni Júdà sì sá kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.
28. Èyí ni iye àwọn ènìyàn tí Nebukadinésárì kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì.Ní ọdún keje ẹgbẹ̀dógún ó lé mẹ́talélógún ará Júdà.