Jeremáyà 38:7-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ṣùgbọ́n, Ebedimélékì, ará Kúṣì ìjòyè nínú ààfin Ọba gbọ́ pé wọ́n ti ju Jeremáyà sínú àmù. Nígbà tí Ọba jókòó lẹ́nubodè Bẹ́ńjámínì.

8. Ebedimélékì jáde kúrò láàfin ó sì sọ fún un pé,

9. “Olúwa mi Ọba, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ti ṣe ohun búburú sí Jeremáyà òjíṣẹ́ Ọlọ́run. Wọ́n ti gbé e sọ sínú àmù níbi tí kò sí oúnjẹ kankan nínú ìlú mọ́.”

10. Nígbà náà ni Ọba pàṣẹ fún Ebedimélékì ará Kúṣì pé, “Mú ọgbọ̀n ọkùnrin láti ibí pẹ̀lú rẹ, kí ẹ sì lọ yọ Jeremáyà òjíṣẹ́ Ọlọ́run kúrò nínú àmù kí ó tó kú.”

11. Ebedimélékì kó àwọn ọkùnrin náà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n lọ sínú yàrá kan nínú ààfin Ọba. Ó mú àwọn aṣọ àkísà àti okùn tọ Jeremáyà lọ nínú àmù.

12. Ebedimélékì sọ fún Jeremáyà pé, “Fi àkísà àti okùn bọ abẹ́ abíyá rẹ, Jeremáyà sì ṣe bẹ́ẹ̀.”

13. Báyìí ni wọ́n ṣe yọ ọ́ jáde, ó sì ń gbé àgbàlá àwọn ẹ̀ṣọ́.

14. Nígbà náà ni Ọba Sedekáyà ránṣẹ́ pe, Jeremáyà òjíṣẹ́ Ọlọ́run àti láti mú un wá sí ẹnubodè kẹta nílé Ọlọ́run. Ọba sì sọ fún Jeremáyà pé, “Èmi yóò bi ọ́ ní ohun kan; má sì ṣe fi ohun kan pamọ́ fún mi.”

15. Jeremáyà sì sọ fún Sedekáyà pé, “Tí mo bá fún ọ ní èsì, ṣé o kò ní pa mí? Tí mo bá gbà ọ́ nímọ̀ràn, o kò ní gbọ́ tèmi.”

16. Ṣùgbọ́n Ọba Sedekáyà búra ní ìkọ̀kọ̀ fún Jeremáyà wí pé, “Dájúdájú bí Olúwa ti ń bẹ, ẹni tí ó fún wa ní ẹ̀mí, èmi kò ní pa ọ́ tàbí fà ọ́ fún àwọn tó ń lépa ẹ̀mí rẹ.”

Jeremáyà 38