6. Ní àkókò ìjọba Jòsáyà Ọba, Olúwa wí fún mi pé, “Ṣé o ti rí nǹkan tí àwọn Ísírẹ́lì aláìnígbàgbọ́ ti ṣe? Wọ́n ti lọ sí àwọn òkè gíga àti sí abẹ́ àwọn igi, wọ́n sì ti ṣe àgbèrè níbẹ̀.
7. Mo rò pé nígbà tí wọ́n ti ṣe èyí wọn yóò padà, wọn kò padà, Júdà aláìgbàgbọ́ arábìnrin rẹ̀ náà sì rí i.
8. Mo fún Ísírẹ́lì aláìnígbàgbọ́ ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀, mo sì ké wọn kúrò nítorí gbogbo àgbèrè wọn. Ṣíbẹ̀ mo rí pé Júdà tí ó jẹ́ arábìnrin rẹ̀ kò bẹ̀rù, òun náà sì jáde lọ láti lọ ṣe àgbèrè.
9. Nítorí ìwà èérí Ísírẹ́lì kò jọ ọ́ lójú, ó ti ba ilẹ̀ jẹ́, ó sì ti ṣe àgbèrè pẹ̀lú òkúta àti igi.
10. Látàrí gbogbo nǹkan wọ̀nyí Júdà arábìnrin rẹ̀ aláìgbàgbọ́ kò padà tọ̀ mí wá pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀, bí kò ṣe nípa fífarahàn bí olótìtọ́,” ni Olúwa wí.
11. Olúwa wí fún mi pé, “Ísírẹ́lì aláìnígbàgbọ́ ṣe òdodo ju Júdà tí ó ní Ìgbàgbọ́ lọ.
12. Lọ polongo ọ̀rọ̀ náà, lọ sí ìhà àríwá:“ ‘Yípadà, Ísírẹ́lì aláìnígbàgbọ́,’ ni Olúwa wí.‘Ojú mi kì yóò le sí yín mọ́,nítorí mo jẹ́ aláàánú, ni Olúwa wí.
13. Sá à ti mọ ẹ̀bi rẹ,o ti ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ,o ti wá ojú rere rẹ lọ́dọ̀ ọlọ́run àjèjìlábẹ́ gbogbo igikígi,tí ó tẹ́wọ́, o kò sì gbọ́ràn sí mi lẹ́nu,’ ”ni Olúwa wí.
14. “Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́,” ni Olúwa wí, “nítorí èmi ni ọkọ rẹ. Èmi ó yàn ọ́, ọ̀kan láti ìlú àti méjì láti ẹ̀yà. Èmi ó sì mú ọ wá sí Síónì.