Jeremáyà 25:4-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa ti rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn wòlíì sí i yín láti ìgbà dé ìgbà, ẹ̀yin kò fetí sílẹ̀.

5. Wọ́n sì wí pé, “Ẹ yípadà olúkúlùkù yín kúrò ní inú ibi rẹ̀ àti ní ọ̀nà ibi rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì lè dúró ní ilẹ̀ tí Ọlọ́run fún un yín àti àwọn baba yín títí láéláé.

6. Má ṣe tọ àwọn Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn láti sìn wọ́n tàbí bọ wọ́n; ẹ má ṣe mú inú bí mi pẹ̀lú ohun tí ẹ ti fi ọwọ́ yín ṣe. Nígbà náà ni Èmi kò ní ṣe yín ní ibi.”

7. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi,” ni Olúwa wí; “bẹ́ẹ̀ ni ẹ sì ti mú inú bí mi pẹ̀lú ohun tí ẹ fi ọwọ́ yín ṣe, ẹ sì ti mú ibi wá sórí ara yín.”

8. Nítorí náà, Ọlọ́run alágbára sọ èyí: “Nítorí wí pé ẹ̀yin kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi,

9. Èmi yóò pe gbogbo àwọn ènìyàn àríwá, àti ìránṣẹ́ mi Nebukadinésárì Ọba Bábílónì,” ni Olúwa wí. “Èmi yóò sì mú wọn dìde lòdì sí ilẹ̀ náà àti àwọn olùgbé rẹ̀ àti sí gbogbo orílẹ̀ èdè àyíká rẹ̀. Èmi yóò pa wọ́n run pátapáta, Èmi yóò sọ wọ́n di nǹkan ẹ̀rù àti yẹ̀yẹ́ àti ìparun ayérayé.

10. Èmi yóò sì mú ìró ayọ̀ àti inú dídùn kúrò lọ́dọ̀ wọn; ohùn ìyàwó àti ọkọ ìyàwó, ìró ọlọ òkúta àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà.

11. Gbogbo orílẹ̀ èdè yìí yóò sì di ahoro, orílẹ̀ èdè yìí yóò sì sìn ní Bábílónì ní àádọ́rin ọdún.

12. “Ṣùgbọ́n, nígbà tí àádọ́rin ọdún náà bá pé; Èmi yóò fi ìyà jẹ Ọba Bábílónì àti orílẹ̀ èdè rẹ, ilẹ̀ àwọn ará Bábílónì nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,” ni Olúwa wí; “bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò sọ ọ́ di ahoro títí láé.

13. Èmi yóò sì mú gbogbo ohun tí mo ti sọ wọ̀nyí wá sórí ilẹ̀ náà, gbogbo ohun tí a ti sọ ani gbogbo èyí tí a ti kọ sínú ìwé yìí, èyí tí Jeremáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ sí gbogbo orílẹ̀-èdè.

14. Àwọn fúnra wọn yóò sì sin orílẹ̀ èdè púpọ̀ àti àwọn Ọba ńlá. Èmi yóò sì sán fún oníkálukú gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti iṣẹ́ ọwọ́ wọn.”

15. Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí fún mi: “Gba aago yìí ní ọwọ́ mí tí ó kún fún ọtí wáìnì ìbínú mi, kí o sì mú gbogbo orílẹ̀ èdè ti mo rán ọ sí mu ún.

16. Nígbà tí wọ́n bá mu ún, wọn yóò ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n: bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n di aṣiwèrè nítorí idà tí mo fi ránṣẹ́ sí àárin wọn.”

17. Mo sì gba aago náà lọ́wọ́ Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni mo sì mú gbogbo orílẹ̀ èdè tí ó rán mi sí mu ún.

18. Jérúsálẹ́mù àti àwọn ìlú Júdà, àwọn Ọba wọn pẹ̀lú àwọn aláṣẹ wọn, láti sọ wọ́n di ohun ìparun, ohun ẹ̀rù, ẹ̀sìn àti ègún, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti rí lónìí yìí.

19. Fáráò Ọba Éjíbítì, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn aláṣẹ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀.

20. Àti gbogbo àwọn ènìyàn àjòjì tí ó wà níbẹ̀; gbogbo àwọn Ọba Húsì, gbogbo àwọn Ọba Fílístínì, gbogbo àwọn ti Áṣíkélónì, Gásà, Ékírónì àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó kù sí Áṣídódì.

Jeremáyà 25