Jeremáyà 25:18-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Jérúsálẹ́mù àti àwọn ìlú Júdà, àwọn Ọba wọn pẹ̀lú àwọn aláṣẹ wọn, láti sọ wọ́n di ohun ìparun, ohun ẹ̀rù, ẹ̀sìn àti ègún, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti rí lónìí yìí.

19. Fáráò Ọba Éjíbítì, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn aláṣẹ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀.

20. Àti gbogbo àwọn ènìyàn àjòjì tí ó wà níbẹ̀; gbogbo àwọn Ọba Húsì, gbogbo àwọn Ọba Fílístínì, gbogbo àwọn ti Áṣíkélónì, Gásà, Ékírónì àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó kù sí Áṣídódì.

21. Édómù, Móábù àti Ámónì

22. Gbogbo àwọn Ọba Tirè àti Sídónì; gbogbo àwọn Ọba erékùṣù wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní ìkọjá òkun.

23. Dédánì, Témà, Búsì àti gbogbo àwọn tí ń gbé lọ́nà jínjìn réré.

24. Gbogbo àwọn Ọba Árábíà àti àwọn Ọba àwọn àjòjì ènìyàn tí ń gbé inú ihà.

25. Gbogbo àwọn Ọba Símírì, Élámù àti Mídíà.

26. Àti gbogbo àwọn Ọba àríwá ní tòsí àti lọ́nà jínjìn, ẹnìkìn-ín-ní lẹ́yìn ẹnìkejì; gbogbo àwọn ìjọba lórí orílẹ̀ ayé. Àti gbogbo wọn, Ọba Ṣéṣákì náà yóò sì mu.

27. “Nígbà náà, sọ fún wọn: Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run alágbára Ísírẹ́lì wí: Mu, kí o sì mu amuyó kí o sì bì, bẹ́ẹ̀ ni kí o sì ṣubú láì dìde mọ́ nítorí idà tí n ó rán sí àárin yín.

28. Ṣùgbọ́n bí wọ́n ba kọ̀ láti gba aago náà ní ọwọ́ rẹ kí wọ́n sì mu ún, sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run alágbára sọ: Ẹyin gbọdọ̀ mu ún!

29. Wò ó, èmi ń mú ibi bọ̀ sí orí orílẹ̀ èdè tí ó ń jẹ́ orúkọ mi; ǹjẹ́ yóò há a lè lọ láìjìyà? Ẹ̀yin ń pe idà sọ̀kalẹ̀ sórí gbogbo àwọn olùgbé ayé, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ.’

Jeremáyà 25