Jẹ́nẹ́sísì 49:3-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. “Rúbẹ́nì, ìwọ ni àkọ́bí mi,agbára mi, ìpìlẹṣẹ̀ ipá mi,títayọ ní ọlá àti títayọ ní agbára.

4. Ẹni ríru bí omi òkun, ìwọ kì yóò tayọ mọ́,nítorí pé ìwọ gun ibùsùn baba rẹ,lórí àkéte mi, ìwọ sì bà á jẹ́(ìwọ bá ọ̀kan nínú àwọn aya baba rẹ lò pọ̀).

5. “Símónì àti Léfì jẹ́ arákùnrin—idà wọn jẹ́ ohun èlò ogun alágbára.

6. Kí ọkàn mi má ṣe ni àṣepọ̀ pẹ̀lú wọn,kí n má sì ṣe dúró níbí ìpéjọpọ̀ wọn,nítorí wọ́n ti pa àwọn ènìyàn ní ìbínú wọn,wọ́n sì da àwọn màlúù lóró bí ó ti wù wọ́n.

7. Ìfibú ni ìbínú wọn nítorí tí ógbóná púpọ̀, àti fún ìrunú wọn nítorí tí ó kún fún ìkà.Èmi yóò tú wọn ká ní Jákọ́bù,èmi ó sì fọ́n wọn ká ní Ísírẹ́lì.

8. “Júdà, àwọn arákùnrin rẹ yóò yìn ọ,ọwọ́ rẹ yóò wà ní ọrùn àwọn ọ̀ta rẹ,àwọn ọmọkùnrin baba rẹ yóò foríbalẹ̀ fún ọ.

9. Ọmọ kìnnìún ni ọ́, ìwọ Júdà,o darí láti ìgbẹ́ ọdẹ, ọmọ mi.Bí i kìnnìún, o ba mọ́lẹ̀, o sì sùn sílẹ̀ bí i abo kìnnìún,Ta ni ó tó bẹ́ẹ̀, kí o lé e dìde?

Jẹ́nẹ́sísì 49