1. Nígbà náà ni Jákọ́bù ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, kí n le è sọ ohun tí yóò sẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú fún-un yín.
2. “Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, kí ẹ sì tẹ́tí, ẹ̀yin ọmọ Jákọ́bù;Ẹ fetí sí Ísírẹ́lì baba yín.
3. “Rúbẹ́nì, ìwọ ni àkọ́bí mi,agbára mi, ìpìlẹṣẹ̀ ipá mi,títayọ ní ọlá àti títayọ ní agbára.
4. Ẹni ríru bí omi òkun, ìwọ kì yóò tayọ mọ́,nítorí pé ìwọ gun ibùsùn baba rẹ,lórí àkéte mi, ìwọ sì bà á jẹ́(ìwọ bá ọ̀kan nínú àwọn aya baba rẹ lò pọ̀).
5. “Símónì àti Léfì jẹ́ arákùnrin—idà wọn jẹ́ ohun èlò ogun alágbára.
6. Kí ọkàn mi má ṣe ni àṣepọ̀ pẹ̀lú wọn,kí n má sì ṣe dúró níbí ìpéjọpọ̀ wọn,nítorí wọ́n ti pa àwọn ènìyàn ní ìbínú wọn,wọ́n sì da àwọn màlúù lóró bí ó ti wù wọ́n.
7. Ìfibú ni ìbínú wọn nítorí tí ógbóná púpọ̀, àti fún ìrunú wọn nítorí tí ó kún fún ìkà.Èmi yóò tú wọn ká ní Jákọ́bù,èmi ó sì fọ́n wọn ká ní Ísírẹ́lì.
8. “Júdà, àwọn arákùnrin rẹ yóò yìn ọ,ọwọ́ rẹ yóò wà ní ọrùn àwọn ọ̀ta rẹ,àwọn ọmọkùnrin baba rẹ yóò foríbalẹ̀ fún ọ.
9. Ọmọ kìnnìún ni ọ́, ìwọ Júdà,o darí láti ìgbẹ́ ọdẹ, ọmọ mi.Bí i kìnnìún, o ba mọ́lẹ̀, o sì sùn sílẹ̀ bí i abo kìnnìún,Ta ni ó tó bẹ́ẹ̀, kí o lé e dìde?
10. Ọ̀pá oyè kì yóò kúrò ní Júdàbẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá-ìsàkóso kì yóò kúròláàrin ẹṣẹ̀ rẹ̀, títí tí ẹni tí ó ni í yóò fi dé,tí gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè yóò máa wárí fún un.
11. Yóò má ṣo ọmọ ẹsin rẹ̀ mọ́ igi àjàrà àtiọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ mọ́ ẹ̀ka tí ó dára jù.Yóò fọ aṣọ rẹ̀ nínú wáìnì àti ẹ̀wùrẹ̀ nù nínú omi-pupa ti eṣo àjàrà (gíréèpù).
12. Ojú rẹ̀ yóò rẹ̀ dòdò ju wáìnì lọ,ẹyín rẹ yóò sì funfunu pẹ̀lú omi-ọyàn