Jẹ́nẹ́sísì 41:19-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Lẹ́yìn wọn, màlúù méje mìíràn jáde wá, wọ́n rù hángógo, wọn kò sì lẹ́wà tóbẹ́ẹ̀ tí n kò tíì rí irú màlúù tí ó ṣe àìlẹ́wà tó bẹ́ẹ̀ rí ní ilẹ̀ Éjíbítì.

20. Àwọn màlúù tí ó rù tí kò sì lẹ́wà sì jẹ àwọn màlúù tí ó sanra tí ó kọ́ jáde nínú odò.

21. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹ́ wọ́n tan, kò sì ẹni tí ó le mọ̀ pé wọ́n jẹ ohunkóhun, nítorí wọn kò sanra sí i, wọn sì búrẹ́wà ṣíbẹ̀. Nígbà náà ni mo jí lójú oorun mi.”

22. “Ní ojú àlá mi, mo tún rí ṣiiri ọkà méje tí ó yó ọmọ tí ó sì dára, wọ́n jáde láti ara igi ọkà kan.

23. Lẹ́yìn wọn, àwọn méje mìíràn yọ jáde, tí kò yó ọmọ bẹ́ẹ̀ ni afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn ti rẹ̀ ẹ́ dànù tán.

24. Àwọn siiri ọkà méje tí kò yó mọ sì gbé àwọn méje tí ó dára wọ̀nyí mì. Mo ṣọ àlá yìí fún àwọn onídán àn mi, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó le è túmọ̀ rẹ̀ fún mi.”

25. Nígbà náà ni Jósẹ́fù wí fún Fáráò, “Ìtúmọ̀ kan náà ni àwọn àlá méjèèjì ní. Ọlọ́run fi ohun tí ó fẹ́ ṣe hàn fún Fáráò.

26. Àwọn màlúù méje ti ó dára jẹ́ ọdún méje, ṣiiri ọkà méje tí ó dára náà sì jẹ́ ọdún méje: ọ̀kan ṣoṣo ni wọn, àlá kan náà ni.

27. Àwọn màlúù méje tí kò sanra, tí kò sì rẹwà tí ó jáde gbẹ̀yìn jẹ́ ọdún méje, bẹ́ẹ̀ náà ni siiri ọkà méje tí kò dára, tí afẹ́fẹ́ ìlà oòrun ti rẹ̀ dànù tan: Wọn jẹ́ ọdún méje tí ìyàn yóò fi mú.

28. “Bí mo ti wí fún Fáráò ní ìṣáájú náà ni: Ọlọ́run fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ han Fáráò.

29. Ọdún méje tí oúnjẹ yóò pọ yanturu ń bọ̀ wà ní Éjíbítì.

Jẹ́nẹ́sísì 41