Jẹ́nẹ́sísì 41:13-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Bí ó sì ti túmọ̀ àlá wọ̀nyí náà ni ohun gbogbo rí. A dá mi padà sí ipò mi, a sì ṣo ọkùnrin keji kọ́ sórí òpó.”

14. Nítorí náà Fáráò ránṣẹ́ pe Jósẹ́fù, wọn sì mu un wá kíákíá láti inú ìhámọ́. Nígbà tí ó fá irun rẹ̀, s tí ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó wá ṣíwájú Fáráò.

15. Fáráò wí fún Jósẹ́fù, “Mo lá àlá kan, kò sì sí ẹni tí o le è túmọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n mo ti gbọ́ nípa rẹ pé bí o bá ti gbọ́ àlá, o le è túmọ̀ rẹ̀”

16. Jóṣẹ́fù dáhùn pé, “kì í ṣe agbára mi, ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ni yóò fún Fáráò ní ìtúmọ̀ àlá náà.”

Jẹ́nẹ́sísì 41