Jẹ́nẹ́sísì 39:13-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Nígbà tí ó rí i pé ó ti fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí òun lọ́wọ́, ó sì ti sá jáde,

14. ó pe àwọn ìránṣẹ́ ilé náà, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wò ó, ọkọ ọ̀ mi mú Ébérù kan wọlé tọ̀ wá láti fi wá ṣe ẹlẹ́yà. Ó wọlé tọ̀ mí wá, láti bá mi lò pọ̀, ṣùgbọ́n mo kígbe.

15. Nígbà tí ó gbọ́ pé mo gbé ohùn mi sokè, tí mo sì kígbe, ó jọ̀wọ́ aṣọ rẹ̀ sọ́dọ̀ mi, ó sì sá, ó bọ́ sóde.”

16. Ó sì fi aṣọ náà sọ́dọ̀ títí tí ọkọ rẹ̀ fi dé.

17. Ó rò fún un pé, “Ẹrú ará a Ébérù tí o rà wálé láti fi wá ṣẹlẹ́yà wá láti bá mi lò pọ̀.

18. Ṣùgbọ́n bí mo ti kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ó sì sá kúrò nínú ilé.”

19. Nígbà tí Pọ́tífà gbọ́ ọ̀rọ̀ aya rẹ̀ pé báyìí ni ẹrú rẹ̀ ṣe sí aya rẹ̀, ó bínú gidigidi.

20. Ó sì ju Jósẹ́fù sí ẹ̀wọ̀n, níbi tí a ń ju àwọn ẹlẹ́wọ̀n ọba sí.Ṣùgbọ́n, nígbà tí Jóṣẹ́fù wà nínú ẹ̀wọ̀n níbẹ̀,

21. Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì sàánú fún un, ó sì mú kí ó rí ojúrere àwọn alábojútó ọgbà ẹ̀wọ̀n (wọ́dà).

Jẹ́nẹ́sísì 39