Jẹ́nẹ́sísì 38:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní àkókò náà, Júdà lọ kúrò lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ láti lọ dúró lọ́dọ̀ ọkùnrin ará Ádúlámù kan tí ń jẹ́ Hírà.

2. Júdà sì pàdé ọmọbìnrin Kénánì kan níbẹ ẹni ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Súà. Ó sì fi ṣe aya, ó sì bá a lò pọ̀;

3. ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, tí ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Érì.

4. Ó sì tún lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin, ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Ónánì.

5. Ó sì tún bí ọmọkùnrin mìíràn, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ṣélà. Ní Késíbù ni ó wà nígbà tí ó bí i.

6. Júdà sì fẹ́ aya fún Érì, àkọ́bí rẹ̀, orúkọ aya náà ni Támárì.

7. Ṣùgbọ́n Érì àkọ́bí Júdà ṣe ènìyàn búburú níwájú Olúwa, Ọlọ́run sì pa á.

8. Nígbà náà ni Júdà wí fún Ónánì, “Bá aya arákùnrin rẹ lò pọ̀, kí o ṣe ojúṣe rẹ fun un gẹ́gẹ́ bí àbúrò ọkọ, kí ó ba à le bí ọmọ fún un ní orúkọ arákùnrin-ìn rẹ.”

9. Ṣùgbọ́n Ónání mọ̀ pé àwọn ọmọ náà kì yóò jẹ́ ti òun, nítorí náà ni gbogbo ìgbà tí ó bá wọlé tọ aya arákùnrin rẹ̀ lọ, ilẹ̀ ni ó ń da nǹkan ọkùnrin rẹ̀ sí, kí ó má bá a bímọ fún arákùnrin rẹ̀.

10. Ohun tí ó ń ṣe yìí burú lójú Olúwa, ó sì pa òun náà pẹ̀lú.

Jẹ́nẹ́sísì 38