2. Obìnrin náà dá ejò lóhùn pé, “Àwá lè jẹ lára àwọn èṣo igi tí ó wà nínú ọgbà,
3. ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ lára èṣo igi tí ó wà láàrin ọgbà, ẹ kò sì gbọdọ̀ fi ọwọ́ kàn án, bí ẹ̀yin bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin yóò kú.’ ”
4. Ejò wí fún obìnrin náà pé, “Ẹ̀yin kì yóò kú ikúkíkú kan.”
5. “Nítorí Ọlọ́run mọ̀ wí pé, bí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀, ojú yín yóò là, ẹ̀yin yóò sì dàbí Ọlọ́run, ẹ̀yin yóò sì mọ rere yàtọ̀ sí búburú.”
6. Nígbà tí obìnrin náà rí i wí pé èṣo igi náà dára fún oúnjẹ àti pé, ó sì dùn ún wò, àti pé ó ń mú ni ní ọgbọ́n, ó mú díẹ̀ níbẹ̀, ó sì jẹ ẹ́. Ó sì mú díẹ̀ fún ọkọ rẹ̀, ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, òun náà sì jẹ ẹ́.
7. Nígbà náà ni ojú àwọn méjèèjì sì là, wọ́n sì mọ̀ pé àwọn wà ní ìhòòhò; wọ́n sì rán ewé ọ̀pọ̀tọ́ pọ̀, wọ́n sì fi bo ara wọn.
8. Nígbà náà ni ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ gbọ́ ìró Olúwa Ọlọ́run bí ó ti ń rìn nínú ọgbà nígbà tí ojú ọjọ́ tura, wọ́n sì fi ara pamọ́ kúrò níwájú Olúwa Ọlọ́run sí àárin àwọn igi inú ọgbà.
9. Ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run ké pe ọkùnrin náà pé, “Níbo ni ìwọ wà?”
10. Ó dáhùn pé, “Mo gbúrò ó rẹ̀ nínú ọgbà, ẹ̀rù sì bà mí nítorí pé, mo wà ní ìhòòhò, mo sì fi ara pamọ́.”
11. Ọlọ́run wí pé, “Ta ni ó wí fún ọ pé ìhòòhò ni ìwọ wà? Ṣé ìwọ ti jẹ nínú èṣo igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀ ni?”
12. Ọkùnrin náà wí pé, “Obìnrin tí ìwọ fi fún mi, ni ó fún mi nínú èṣo igi náà, mo sì jẹ ẹ́.”
13. Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe yìí?”Obìnrin náà dáhùn pé, “Ejò ni ó tàn mí jẹ, mo sì jẹ ẹ́.”
14. Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí fún ejò náà pé, “Nítorí tí ìwọ ti ṣe èyí,“Ègún ni fún ọ ju gbogbo ohun ọ̀sìnàti gbogbo ẹran igbó tó kù lọ!Àyà rẹ ni ìwọ yóò fi máa wọ́,ìwọ yóò sì máa jẹ erùpẹ̀ ilẹ̀ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.