Jẹ́nẹ́sísì 27:6-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Rèbékà sọ fún Jákọ́bù ọmọ rẹ̀ pé, “Wò ó, mo gbọ́ tí baba rẹ ń bá ẹ̀gbọ́n rẹ sọ̀rọ̀ pé,

7. ‘Pa ẹran fún mi wá, kí o sì se oúnjẹ àdídùn fún mi láti jẹ, kí n baà le súre fún ọ níwájú Olúwa kí èmi tó kú.’

8. Nísinsin yìí ọmọ mi, gbọ́ tèmi kí o sì ṣe ohun tí èmi yóò wí fún ọ:

9. Lọ sínú agbo ẹran, kí o sì mú ọmọ ewúrẹ́ méjì, kí ó lè ṣe oúnjẹ́ àdídùn fún baba rẹ, irú èyí tí ó fẹ́ràn dáradára.

10. Ìwọ yóò sì gbé e tọ baba rẹ lọ, kí òun baà lè jẹ ẹ́, kí ó sì súre fún ọ kí ó tó kú.”

11. Jákọ́bù sì wí fún Rèbékà ìyá rẹ̀ pé, “Ṣùgbọ́n Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n mi jẹ́ ènìyàn onírun lára bẹ́ẹ̀ alára ọ̀bọ̀rọ́ ni mi,

12. Bí baba mi bá fọwọ́ kàn mi ńkọ́? Èmi yóò jọ ẹlẹ́tàn lójú rẹ̀, dípò kí ó súre fún mi, èmi yóò sì mú ègún wá sórí ara mi.”

13. Mọ̀mọ́ rẹ̀ wá wí fun un pé, “Ọmọ mi jẹ́ kí ègún náà wá sórí mi, ṣáà ṣe ohun tí mo wí kí o sì mú àwọ̀ ẹran náà wá fún mi.”

14. Jákọ́bù sì ṣe ohun gbogbo tí ìyá rẹ̀ wí fun un, Rèbékà sì se oúnjẹ àdídùn náà, irú èyí tí Ísáákì fẹ́ràn.

15. Nígbà náà ni Rèbékà mú èyí tí ó dára jù nínú aṣọ Ísọ̀ ọmọ rẹ̀ àgbà tí ó wà nínú ilé Rèbékà, ó sì fi wọ Jákọ́bù ọmọ rẹ̀ kékeré.

16. Ó sì fi awọ ewúrẹ́ wọ̀n-ọn-nì bo ọwọ́ àti ibi tí ó yọ silẹ̀ lọ́rùn rẹ̀ tí kò ní irun.

17. Nígbà náà ni ó gbé ẹran dídùn náà àti oúnjẹ tí ó ti sè lé Jákọ́bù ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́.

18. Jákọ́bù wọlé lọ sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ ó sì wí pé, “Baba mi”,Baba rẹ sì dáhùn pé, “Èmi nìyí, ìwọ ta ni, ọmọ mi?”

Jẹ́nẹ́sísì 27