Jẹ́nẹ́sísì 27:23-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Kò sì dá Jákọ́bù mọ̀ nítorí ọwọ́ rẹ̀ nírun bí i ti Ísọ̀ arákùnrin rẹ, nítorí náà, ó súre fún-un

24. ó sì bi í léèrè pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ni Éṣáù ọmọ mi ni tòótọ́?”Jákọ́bù sì dáhùn pé, “Èmi ni.”

25. Nígbà náà ni Ísáákì wí pé “Gbé ẹran igbó náà súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi, kí èmi kí ó jẹ ẹ́, kí èmi sì súre fún ọ láti inú ọkàn mi wá.”Jákọ́bù sì gbé e wá ó sì jẹ ẹ́, ó sì tún fún-un ní wáìnì, ó sì mú un pẹ̀lú.

26. Nígbà náà ni Ísáákì baba rẹ̀ wí fun un pé, “Súnmọ mi, ọmọ mi, kí o sì fẹnu kò mí ní ẹnu.”

27. Ó sì súnmọ ọn, ó sì fẹnu kò ó ní ẹnu. Nígbà tí Ísáákì gbọ́ òórùn aṣọ rẹ̀, ó súre fún-un ó wí pé:“Wò ó òórùn ọmọ miDà bí òórùn okotí Olúwa ti bùkún.

28. Kí Olúwa kí ó fún ọ ní ìrì ọ̀runàti nínú ọ̀rá ilẹ̀àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ àti wáìnì túntún.

29. Kí àwọn orílẹ̀-èdè kí ó máa sìn ọ́,kí àwọn ènìyàn sì máa tẹríba fún ọ,máa ṣe olórí àwọn arákùnrin rẹ,kí àwọn ìyekan rẹ sì máa wólẹ̀ fún ọÈgún ni fún gbogbo ẹni tí ń fi ọ́ ré,Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó súre fún ọ.”

30. Bí Ísáákì ti súre tan tí Jákọ́bù ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde kúrò ní ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ ni Ísọ̀ ti oko ọdẹ dé.

31. Òun pẹ̀lú ṣe ẹran dídùn, ó sì gbé e tọ baba rẹ̀ wá, ó sì wí fún un pé, “Baba mi, dìde jókòó, kí o sì jẹ nínú ẹran igbó tí mo ti ṣè, kí o sì súre fún mi.”

32. Ìsáákì baba rẹ̀ sì bi í wí pé, “Ìwọ ta ni?” Ó sì dáhùn pé “Èmi Ísọ̀, àkọ́bí rẹ ni.”

33. Nígbà náà ni Ísáákì wárìrì gidigidi, ó sì wí pé, “Ta ni ẹni náà, tí ó ti pa ẹran igbó tí ó sì ti gbe wá fún mi, tí mo sì ti jẹ ẹ́ kí ó tó dé? Mo sì ti súre fún un sì wò ó dájúdájú a ó sì bùkún un”

Jẹ́nẹ́sísì 27