18. Ísáákì sì ṣe àtúngbẹ́ àwọn kànga tí baba rẹ̀ ti gbẹ́ nígbà ayé rẹ̀, èyí tí àwọn Fílístínì ti dí lẹ́yìn ikú baba rẹ̀, ó sì fún wọn lórúkọ tí baba rẹ̀ ti sọ wọ́n tẹ́lẹ̀.
19. Àwọn ìránṣẹ́ Ísáákì sì gbẹ́ kànga ní àfonífojì náà, wọ́n kan ìsun omi níbẹ̀.
20. Ṣùgbọ́n àwọn darandaran Gérárì ń bá àwọn darandaran Ísáákì jà sí kànga náà pé àwọn ni àwọn ni ín. Nítorí náà ni ó fi pe orúkọ kànga náà ní Éṣékì, nítorí pé wọ́n bá a jà sí kànga náà.
21. Àwọn ìránṣẹ́ Isáákì tún gbẹ́ kànga mìíràn, wọ́n sì tún jà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Ṣìtínà (kànga àtakò).
22. Ó sì tún kúrò níbẹ̀, ó sì gbẹ́ kànga mìíràn, wọn kò sì já sí èyí rárá, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Réhóbótì, ó wí pé, “Nísinsìnyìí, Olúwa ti fi àyè gbà wá, a ó sí i gbilẹ̀ sì ni ilẹ̀ náà.”
23. Láti ibẹ̀, ó kúrò lọ sí Bíáṣébà.
24. Ní òru ọjọ́ tí ó dé ibẹ̀, Olúwa sì fara hàn-án, ó sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù baba rẹ: Má ṣe bẹ̀rù nítorí èmi wà fún ọ, èmi yóò sì sọ iye ìran rẹ di púpọ̀, nítorí Ábúráhámù ìránṣẹ́ mi.”
25. Ísáákì sì kọ́ pẹpẹ kan ṣíbẹ̀, ó sì pe orúkọ Olúwa. Níbẹ̀ ni ó pàgọ́ rẹ̀ sí, àwọn ìránṣẹ́ rẹ sì gbẹ́ kànga kan ṣíbẹ̀.
26. Nígbà náà ni Ábímélékì tọ̀ ọ́ wá láti Gérárì, àti Áhúsátì, olùdámọ̀ràn rẹ̀ àti Fíkólì, olórí ogun rẹ̀.