1. Ṣárà sì pé ọmọ ọdún mẹ́tà-dín-láàádóje (127)
2. ó sì kú ní Kíríátì-Áríbà (ìyẹn ní Hébúrónì) ní ilẹ̀ Kénánì, Ábúráhámù lọ láti sọ̀fọ̀ àti láti sunkún nítorí Ṣárà.
3. Ábúráhámù sì dìde lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú aya rẹ̀, ó sì sọ fún àwọn ará Hítì wí pé,
4. “Iwo jẹ́ àjèjì àti àlejò láàrin yín, ẹ ta ilẹ̀ ìsìnkú fún mi kí èmi le sin òkú tí ó kú fún mi sí.”
5. Àwọn ará Hítì dá a lóhùn pé,
6. “Olúwa mi, gbọ́ tiwa, ó jẹ́ alágbára ọmọ-aládé láàrin wa, sin òkú rẹ sí ibojì tí ó dárajù nínú àwọn ibojì wa, kò sí ẹni tí yóò fi ibojì rẹ dùn ọ́ láti sin òkú rẹ sí.”