Jẹ́nẹ́sísì 20:10-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ábímélékì sì bi Ábúráhámù pé, “Kín ló dé tí ìwọ fi ṣe èyí?”

11. Ábúráhámù sì dáhùn pé, “Mo ṣe èyí nítorí mo rò nínú ara mi pé, ẹ̀yin tí ẹ wà níhìn-ín, ẹ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, pé, ẹ sì le pa mí nítorí aya mi.

12. Yàtọ̀ fún ìyẹn, òtítọ́ ni pé arábìnrin mi ni. Ọmọ baba kan ni wá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a kì í ṣe ọmọ ìyá kan. Mo sì fẹ́ ẹ ní aya.

13. Nígbà tí Ọlọ́run sì mú mi rìn kiri kúrò ní ilé baba mi, mo wí fún un pé, ‘Èyí ni ọ̀nà tí ó lè gbà fi hàn pé ó fẹ́ràn mi: Gbogbo ibi tí a bá dé máa sọ pé, “Arákùnrin rẹ ni mí.” ’ ”

14. Nígbà náà ni Ábímélékì mú àgùntàn àti màlúù wá, àti ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ó sì kó wọn fún Ábúráhámù, ó sì dá Sárà aya rẹ̀ padà fún un.

15. Ábímélékì sì tún wí fún un pé, “Gbogbo ilé mí nìyí níwájú rẹ, máa gbé ní ibikíbi tí o fẹ́ níbẹ̀.”

16. Ábímélékì sì wí fún Ṣárà pé, “Mo fi ẹgbẹ̀rún owó ẹyọ fàdákà fún arákùnrin rẹ. Éyí ni owó ìtanràn ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ níwájú gbogbo ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ àti pé, a dá ọ láre pátapáta.”

17. Nígbà náà, Ábúráhámù gbàdúrà sí Ọlọ́run, Ọlọ́run sì wo Ábímélékì àti aya rẹ̀ àti àwọn ẹrúbìnrin rẹ̀ sàn. Wọ́n sì tún ń bímọ.

18. Nítorí Ọlọ́run ti ṣé gbogbo ará ilé Ábímélékì nínú nítorí Sárà aya Ábúráhámù.

Jẹ́nẹ́sísì 20