Jẹ́nẹ́sísì 16:12-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Òun yóò jẹ́ ẹhànnà ènìyànyóò máa tako gbogbo ènìyàn,gbogbo ènìyàn yóò sì máa takò ó,kì yóò sì bá awọn arákùnrin rẹ̀gbé ní ìrẹ́pọ̀.”

13. Ó sì fi pe Olúwa tí o bá sọ̀rọ̀ ní, “Ìwọ ni Ọlọ́run tí ó rí mi,” nítorí tí ó wí pé, “Mo ti ri ẹni tí ó rí mi báyìí.”

14. Nítorí náà ni a ṣe ń pe kànga náà ní Beeri-Lahai-Róì: kànga ẹni alààyè tí ó rí mi. Ó wà lágbedeméjì Kédásì àti Bérédì.

15. Ágárì sì bí ọmọkùnrin kan fún Ábúrámù, Ábúrámù sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ísímáélì.

16. Ábúrámù jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndín-láàádọ́rùn-ún (86) nígbà tí Hágárì bí Ísímáélì fún-un.

Jẹ́nẹ́sísì 16