5. Olúwa sì mú Ábúrámù jáde síta ó sì wí fún un pé, “Gbójú sókè sí ọ̀run kí o sì ka àwọn ìràwọ̀-bí ó bá ṣe pé ìwọ le è kà wọ́n.” Ó sì wí fun un pé, “Nítorí náà, báyìí ni irú ọmọ rẹ yóò rí.”
6. Ábúrámù sì gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sì òdodo fun-un.
7. Ó sì tún wí fún un pé, “Èmi ni Olúwa tí ó mú ọ jáde láti Úrì ti Kálídéà láti fún ọ ní ilẹ̀ yìí láti jogún.”