Jẹ́nẹ́sísì 15:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn èyí, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Ábúrámù wá lójú ìran pé:Ábúrámù má ṣe bẹ̀rù,Èmi ni ààbò rẹ,Èmi sì ni èrè ńlá rẹ.

2. Ṣùgbọ́n Ábúrámù wí pé, “Olúwa, alágbára, kí ni ìwọ yóò fi fún mi níwọ̀n ìgbà tí èmi kò bímọ, Élíásérì ará Dámásíkù ni yóò sì jogún mi,”

3. Ábúrámù sì tún tẹ̀ṣíwájú pé, “Ìwọ kò fún mi ní ọmọ, nítorí náà ẹrú nínú ilé è mi sì ni yóò jẹ́ àrólé mi.”

4. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ̀ ọ́ wá pé: “Ọkùnrin yìí kọ́ ni yóò jẹ́ àrólé (ajogún) rẹ bí kò ṣe ọmọ tí ìwọ bí fúnrarẹ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ.”

Jẹ́nẹ́sísì 15