Jẹ́nẹ́sísì 11:25-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Ó sì wà láàyè fún ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́fà (119) lẹ́yìn ìbí Tẹ́rà, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

26. Lẹ́yìn tí Tẹ́rà pé ọmọ àádọ́rin ọdún (70) ó bí Ábúrámù, Náhórì àti Háránì.

27. Wọ̀nyí ni ìran Tẹ́rà: Tẹ́rà ni baba Ábúrámù, Náhórì àti Áránì, Áránì sì bí Lọ́tì.

28. Áránì sì kú ṣáájú Tẹ́rà baba rẹ̀ ní ilẹ̀ ìbí rẹ̀ ní Úrì ti ilẹ̀ Kálídéà.

Jẹ́nẹ́sísì 11