Jẹ́nẹ́sísì 1:3-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà,” ìmọ́lẹ̀ sì wà.

4. Ọlọ́run rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì ya ìmọ́lẹ̀ náà sọ́tọ̀ kúrò lára òkùnkùn.

5. Ọlọ́run sì pe ìmọ́lẹ̀ náà ní “Ọ̀sán” àti òkùnkùn ní “Òru.” Àsálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní.

6. Ọlọ́run sì wí pé “Jẹ́ kí òfuurufú kí ó wà ní àárin àwọn omi láti pààlà sí àárin àwọn omi.”

7. Ọlọ́run sì dá òfuurufú láti ya omi tí ó wà ní òkè òfuurufú kúrò lára omi tí ó wà ní orí ilẹ̀. Ó sì rí bẹ́ẹ̀.

8. Ọlọ́run sì pe òfúurufú ní “Ọ̀run,” àsálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kejì.

9. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi abẹ́ ọ̀run wọ́ papọ̀ sí ojúkan, kí ilẹ̀ gbígbẹ sì farahàn.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.

Jẹ́nẹ́sísì 1