1. Síwájú sí i, ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ ohun tí ó wà níwájú rẹ, jẹ ìwé tí a ká yìí; kí o sì lọ fi bá ilé Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀.”
2. Mo sì ya ẹnu mi, ó sì mú mi jẹ ìwé kíká náà.
3. Ó tún sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ ìwe tí mo fún ọ yìí, fi bọ́ inú àti ikùn rẹ.” Nígbà náà ni mo jẹ ẹ́, dídùn rẹ̀ dàbí oyin ní ẹnu mi.
4. Ó sì tún sọ fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, lọ ni ìsinsinyìí bámi sọ ọ̀rọ̀ mi fún ìle Ísírẹ́lì.
5. A kò rán ọ sí àwọn tó ń sọ èdè àjèjì tàbí tí èdè wọn ṣòro láti gbọ́, ṣùgbọ́n orílẹ̀ èdè Ísírẹ́lì ni mo rán ọ sí
6. kì í ṣe sí ọ̀pọ̀ ènìyàn tó ń sọ àjèjì èdè tàbí tí èdè wọn ṣòro láti gbọ́, àwọn tí ọ̀rọ̀ wọn le fún ọ láti gbọ́ yé. Dájúdájú bí mo bá rán ọ sí wọn, wọn ì bá sì fetí sílẹ̀ sí ọ.
7. Ṣùgbọ́n ilé Ísírẹ́lì kò fẹ́ gbọ́ tìrẹ nítorí pé wọn kò fẹ́ láti gbọ́ tèmi, torí pé aláìgbọ́ràn àti ọlọ́kàn líle ni gbogbo ilé Ísírẹ́lì.