Ísíkẹ́lì 27:14-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. “ ‘Àwọn ti ilé Béti Tógárímà ṣe ìpààrọ̀ ẹṣin-ìṣiṣẹ́, ẹṣin-ogun àti ìbàákà ṣòwò ní ọjà rẹ.

15. “ ‘Àwọn ènìyàn Ródísì ni àwọn oníṣòwò rẹ, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù ni wọ́n jẹ́ onibárà rẹ̀; wọ́n mú eyín-erin àti igi ébónì san owó rẹ.

16. “ ‘Árámù ṣòwò pẹ̀lú nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ òwò rẹ̀; wọn ṣe ìpààrọ̀ òkúta iyebíye, òwú elésèé àlùkò, iṣẹ́ ọ̀nà tí a fi abẹ́rẹ́ ṣe, asọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ìlẹ̀kẹ̀ iyùn pupa fún ọjà títà rẹ.

17. “ ‘Júdà àti Ísírẹ́lì, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọn ṣe ìpààrọ̀ ọkà, Mínnítì, àkàrà àdídùn; pannági, oyin, epo àti ìpara olóòórùn dídùn ni wọ́n fi ná ọjà rẹ.

18. “ ‘Dámásíkù, ni oníṣòwò rẹ, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọjà tí ó ṣe àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀; ní ti ọtí wáìnì tí Helíbónì, àti irun àgùntàn funfun.

19. “ ‘Àwọn ará Dánì àti Gíríkì láti Úsálì ra ọjà títà rẹ; irin dídán, káṣíà ati kálámù ni àwọn ohun pàsípààrọ̀ ní ọjà rẹ.

20. “ ‘Dédánì ni oníṣòwò rẹ ní aṣọ ìjókòó-lẹ́sin fún ẹṣin-gígùn.

21. “ ‘Àwọn ará Árábù àti gbogbo àwọn ọmọ aládé Kédárì àwọn ni àwọn onibárà rẹ: ní ti ọ̀dọ́ àgùntàn, àgbò àti ewúrẹ́, nínú ìwọ̀nyí ni wọ́n ti jẹ́ oníbárà rẹ.

Ísíkẹ́lì 27