Ísíkẹ́lì 16:14-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Òkìkí rẹ sì kàn káàkiri orílẹ̀ èdè nítorí ẹwà rẹ, nítorí dídán tí mo fi ṣe ẹwà rẹ láṣe pé, ni Olúwa Ọlọ́run wí.

15. “ ‘Ṣùgbọ́n, o gbẹ́kẹ̀lé ẹwà rẹ, o sì di alágbérè nítorí òkìkí rẹ. O sì fọ́n oju rere rẹ káàkiri sórí ẹni yòówù tó ń kọjá lọ, ẹwà rẹ sì di tìrẹ.

16. O mú lára àwọn aṣọ rẹ, láti rán aṣọ aláràbarà fún ibi giga òrìṣà tí o ti ń ṣàgbèrè. Èyí kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀, tàbí kó tilẹ̀ ṣẹlẹ̀ rárá.

17. O tún mú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ dáradára tí mo fi wúrà àti fàdákà ṣe fún ọ láti fi yá ère ọkùnrin tí ó ń bá ọ ṣe àgbèrè papọ̀.

18. O sì wọ ẹ̀wù oníṣẹ́ ọnà rẹ fún wọn, o sì tún gbé òróró àti tùràrí mi sílẹ̀ níwájú wọn.

19. O tún gbé oúnjẹ tí mo fún ọ-ìyẹ̀fún dáradára, òróró àti oyin-fún wọn gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun olóòórùn dídùn; ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyìí, ni Olúwa Ọlọ́run wí.

20. “ ‘Àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin tí o bí fún mi lo ti fi rúbọ bí oúnjẹ fún àwọn òrìṣà. Ṣé ìwà àgbèrè rẹ kò ha tó bí?

21. Ẹ dú àwọn ọmọ mí lọ́rùn, o fà wọ́n fún ère gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun,

22. Nínú gbogbo iṣẹ́ ìríra àti ìwà àgbérè rẹ, o kò rántí ìgbà èwe rẹ, nígbà tó o wà ní ìhòòhò, tó ń jàgùdù nínú ẹ̀jẹ̀.

23. “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí, ‘Ègbé! Ègbé ni fún ọ. Lẹ́yìn gbogbo ìwà búburú rẹ,

24. O kọ́lé amọ̀ fún ara rẹ, o sì kọ́ ojúbọ gíga sí gbogbo òpin oju pópó.

25. Ní gbogbo òpin ojú pópó lo kọ ojúbọ gíga sí tó o sì fi ẹwà rẹ̀ wọlé, o sọ àgbèrè rẹ di púpọ̀ nípa fífi ara rẹ sílẹ̀ fún gbogbo ẹni tó ń kọjá lọ.

26. O ṣe àgbèrè pẹ̀lú ará Éjíbítì tí í ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ aládúgbò rẹ láti mú mi bínú pẹ̀lú ìwà àgbèrè rẹ tó ń pọ̀ sí i.

27. Nítorí náà ni mo fi na ọwọ mi lòdì sí ọ, mo ge ilé rẹ kúrú; èmi yóò sì mú ìfẹ́ àwọn to korìíra rẹ ṣẹ́ lé ọ lórí, àwọn ọmọbìnrin Fílístínì ti ìwàkiwà rẹ̀ jẹ ìyàlẹ́nu fún,

28. Nítorí àìnítẹ́lọ́rùn rẹ o ṣàgbérè pẹ̀lú ara Ásíríà; síbẹ̀ náà, o kò tún ní ìtẹ́lọ́rùn.

29. Ìwà àgbèrè rẹ tún tẹ̀ṣíwájú dé ilẹ̀ oniṣòwò ni Bábílónì síbẹ̀ náà, o kò tún ni ìtẹ́lọ́rùn.

Ísíkẹ́lì 16