27. Ṣùgbọ́n Bánábà mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ àwọn àpósítélì, ó sì sọ fún wọn bí ó ti rí Olúwa ní ọ̀nà, àti bí ó ti fi ìgboyà wàásù ní Dámásíkù ní orúkọ Jésù.
28. Ó sì pẹ̀lú wọn, ó ń wọlé, ó sì ń jáde ní Jerúsálémù.
29. Ó sì ń fi ìgboyà wàásù ni orúkọ Jésù Olúwa, ó ń sọ̀rọ̀ lòdì sí àwọn ará Hélénì, ó sì ń jà wọ́n níyàn; ṣùgbọ́n wọn ń pète láti pa a.
30. Nígbà tí àwọn arákùnrin sì mọ̀, wọ́n mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kesaríà, wọ́n sì rán an lọ sí Tásísì.
31. Nígbà náà ni ìjọ wà ni àlàáfíà yíká gbogbo Jùdíà àti ni Gálílì àti ni Samaríà, wọn ń fẹsẹ̀múlẹ̀, wọn ń rìn ní ìbẹ̀rù Olúwa, àti ni ìtùnú Ẹ̀mí Mímọ́, wọn ń pọ̀ sí i
32. Ó sì ṣe, bí Pétérù ti ń kọjá lọ káàkiri láàrin wọn, ó sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú si ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ ti ń gbé ni Lídà.
33. Níbẹ̀ ni ó rí ọkùnrin kan ti a pè ní Áénéà tí ó ti dùbúlẹ̀ lórí àkéte ni ọdún mẹ́jọ, ó ní àrùn ẹ̀gbà.