Ìṣe Àwọn Àpósítélì 3:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ó sì fà á lọ́wọ́ ọ̀tún, ó sì gbé dìde; lójúkán náà ẹsẹ̀ rẹ̀ àti egungun kókósẹ̀ rẹ̀ sì mókun.

8. Ó sì ń fò sókè, ó dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn, ó sì bá wọn wọ inú tẹ́ḿpìlì lọ, ó ń rìn, ó sì ń fò, ó sì yín Ọlọ́run.

9. Gbogbo ènìyàn sì rí i, ó ń rìn, ó sì yin Ọlọ́run:

10. Wọn sì mọ̀ pé òun ni ó ti jókòó tí ń ṣagbe lẹ́nu ọ̀nà Dáradára ti tẹ́ḿpìlì náà; hà, sì ṣe wọn, ẹnu sì yà wọn gidigidi sí ohun tí ó ṣe lára rẹ̀.

11. Bí arọ ti a mú láradá sì ti di Pétérù àti Jòhánù mú, gbogbo ènìyàn júmọ́ sure tọ̀ wọ́n lọ ni ìloro ti a ń pè ní ti Sólómónì, pẹ̀lú ìyàlẹ́nú ńlá.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 3