Ìṣe Àwọn Àpósítélì 2:23-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ẹni tí a ti fi lé yín lọ́wọ́ nípa ìpinnu ìmọ̀ àti ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run; àti ẹ̀yin pẹ̀lú, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú kàn mọ́ àgbélébùú, tí a sì pa á.

24. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí díde kúrò nínú òkú, gbà á kúrò nínú ìrora ikú: nítorí tí kò ṣe é ṣe fún ikú láti dì í mú.

25. Dáfídì tí wí nípa tirẹ̀ pé:“ ‘Mo rí Olúwa nígbà gbogbo niwájú mí,nítorí tí ó ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún mi,A kì ó ṣí mi ní ipò.

26. Nítorí náà inú mi dùn, ahọ́n mi sì yọ̀:pẹ̀lúpẹ̀lú ara mi yóò sì sinmi ní ìrètí.

27. Nítorí tí ìwọ kí yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ ni isà-òkú,bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni-Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 2