Ìṣe Àwọn Àpósítélì 19:38-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

38. Ǹjẹ́ nítorí náà tí Démétíríù, àti àwọn oníṣẹ́-ọnà tí o wà pẹ̀lú rẹ̀ bá ní gbólóhùn-asọ̀ kan sí ẹnìkẹ́ni, ilé-ẹjọ́ ṣí sílẹ̀, àwọn onídájọ́ sì ń bẹ: jẹ́ kí wọn lọ fi ara wọn sùn.

39. Ṣùgbọ́n bí ẹ ba ń wádìí ohun kan nípa ọ̀ràn mìíràn, a ó parí rẹ̀ ni àjọ tí ó tọ́.

40. Nítorí àwa ṣa wà nínú èwu, nítórí rògbòdìyàn tí ó bẹ́ sílẹ̀ lóní yìí; kò sáá ní ìdí kan tí ìwọ́jọ yìí fi bẹ́ sílẹ̀.”

41. Nígbà tí ó sì ti sọ bẹ́ẹ̀ tan, ó tú ìjọ náà ká.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 19