22. Pọ́ọ̀lù si dìde dúró láàrin Áréópágù, ó ní, “Ẹ̀yin ará Áténì, mo wòye pé ní ohun gbogbo ẹ kún fún onírúurú ìsìn jù.
23. Nítorí bí mo ti ń kọjá lọ, tí mo wo àwọn ohun tí ẹ̀yin ń sìn, mo sì rí pẹpẹ kan tí a kọ àkọlé yìí ṣí, ‘FÚN ỌLỌ́RUN ÀÌMỌ̀.’ Ǹjẹ́ ẹni tí ẹyin ń sìn ni àìmọ̀ òun náà ni èmi ń ṣọ fún yin.
24. “Ọlọ́run náà tí ó dá ayé àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, òun náà tí í ṣe Olúwa ọ̀run àti ayé, kì í gbé ilé tí a fi ọwọ́ kọ́;
25. Bẹ́ẹ̀ ni a kì í fi ọwọ́ ènìyàn sìn ín, bí ẹni pé ó ń fẹ́ nǹkan, òun ni ó fi ìyè àti èémí àti ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn.
26. Ó sì tí tipàṣẹ̀ ẹnìkan dá gbogbo orílẹ̀-èdè láti tẹ̀dó sí ojú àgbáyé, ó sì ti pinnu àkókò tí a yàn tẹ́lẹ̀, àti ààlà ibùgbé wọn;
27. kí wọ́n baà lè maa wá Olúwa, bóyá wọn yóò lè sàfẹrí rẹ̀, ki wọn sì rí í. Bí ó tílẹ̀ jẹ pé kò jìnnà sí olúkúlùkù wa:
28. Nítorí nínú rẹ̀ ni àwa wà láàyè, tí a ń rìn kiri, tí a sì ní ẹ̀mí wa: bí àwọn kan nínú àwọn akéwì tí ẹ̀yin tìkarayín tí wí pé, ‘Àwa pẹ̀lú sì jẹ́ ọmọ rẹ̀.’