Ìṣe Àwọn Àpósítélì 16:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀kánkán Mísíà, wọ́n gbìyànjú láti lọ ṣí Bítíníà, ṣùgbọ́n Ẹ̀mí Jéṣù kò gbà fún wọn.

8. Nígbà tí wọ́n sì kọjà lẹ́bá Mísíà, wọ́n ṣọ̀kalẹ̀ lọ ṣi Tíróásì.

9. Ìran kan si hàn sì Pọ́ọ̀lù ni òru: Ọkùnrin kan ará Makedóníà dúró, ó sì ńbẹ̀ ẹ̀, wí pé, “Rékọjá wá ṣí Makedóníà, kí o sí ràn wá lọ́wọ́!”

10. Nígbà tí ó sì tí rí ìran náà, lọ́gán ó múra láti lọ sí Makedóníà, a gbà á sí pé, Olúwa tí pè wá láti wàásù ìyìn rere fún wọn.

11. Nítorí náà nígbà tí àwa ṣíkọ̀ ní Tíróáṣì a ba ọ̀nà tàrà lọ ṣí Sámótírakíà, ni ijọ́ kéjì a sì dé Níápólì;

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 16