Ẹkún Jeremáyà 1:4-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ Ṣíónì ń sọ̀fọ̀,nítorí kò sẹ́ni tí ó wá láti jọ́sìn.Ẹnu bodè pátapáta ni ó dahoro,àwọn Olórí àlùfáà ibẹ̀ kérora,àwọn ọ̀dọ́bìnrin rẹ̀ sì ń kẹ́dùn,òun gan-an wà pẹ̀lú ìbànújẹ́ ọkàn.

5. Aninilára rẹ̀ gbogbo di olúwa rẹ̀,nǹkan sì rọrùn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀, Olúwa ti fún un ní ìjìyà tó tọ́nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.Àwọn ẹ̀ṣọ́ wẹ́wẹ́ rẹ̀ lọ sí oko ẹrú,ìgbèkùn níwájú àwọn ọ̀tá.

6. Gbogbo ẹwà ti di ohun ìgbàgbé.Àwọn ọmọ ọba kùnrin dàbí i ìgalàtí kò rí ewé tútù jẹ;nínú àárẹ̀ wọ́n sáréníwájú ẹni tí ó ń lé wọn.

7. Ní ọjọ́ ìpọ́njú àti àrìnká rẹ̀ niJérúsálẹ́mù rántí àwọn ohun ìní dáradára rẹ̀tí ó jẹ́ tirẹ̀ ní ọjọ́ pípẹ́.Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ṣubú sọ́wọ́ àwọn ọ̀tá,kò sì sí olùrànlọ́wọ́ fún un.Àwọn ọ̀tá rẹ̀ wò ówọ́n sì ń fi ìparun rẹ̀ ṣẹlẹ́yà.

8. Jérúsálẹ́mù sì ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀ó sì ti di aláìmọ́.Àwọn tí ó ń tẹríba fún un sì kẹ́gàn rẹ̀,nítorí wọ́n ti rí ìhòòhò rẹ̀;ó kérora fúnra rẹ̀,ó sì lọ kúrò.

9. Ìdọ̀tí wà ní etí aṣọ rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò wo ọjọ́ iwájú rẹ̀,Ìṣubú rẹ̀ ya ni lẹ́nu;olùtùnú kò sì sí fún un.“Wo ìpọ́njú mi, Olúwa,nítorí àwọn ọ̀ta ti borí.”

10. Ọ̀tá ti gbọ́wọ́ légbogbo ìní rẹ;o rí àwọn ìlú abọ̀rìṣàtí wọ́n wọ ibi mímọ́ rẹ—àwọn tí o ti kọ̀ sílẹ̀láti wọ ìpéjọpọ̀ rẹ.

11. Àwọn ènìyàn rẹ̀ ń kérorabí wọ́n ti ń wá oúnjẹ;wọ́n fi ohun ìní wọn se pàsípààrọ̀ oúńjẹláti mú wọn wà láàyè.“Wò ó, Olúwa, kí o sì rò ó,nítorí a kọ̀ mí sílẹ̀.”

12. “Kò ha jẹ́ nǹkankan sí i yín?Gbogbo ẹ̀yin tí ń ré kọjá,Ǹjẹ́ ẹnìkan ń jìyà bí èmi ti ń jìyàtí a fi fún mi, ti Olúwa mú wá fún miní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ̀.

13. “Ó rán iná láti òkèsọ̀kalẹ̀ sínú egungun ara mi.Ó dẹ àwọ̀n fún ẹsẹ̀ mi,ó sì yí mi padà.Ó ti pa mí láramó ń kú lọ ní gbogbo ọjọ́.

14. “Ẹ̀ṣẹ̀ mi ti di síṣopọ̀ sí àjàgà;ọwọ́ ọ rẹ̀ ni a fi hun ún papọ̀.Wọ́n ti yí ọrùn mi ká Olúwa sì ti dín agbára mi kù.Ó sì ti fi mí léàwọn tí n kò le dojúkọ lọ́wọ́.

15. “Olúwa kọàwọn akọni mi sílẹ̀,ó rán àwọn ológun lòdì sí mikí wọn pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi run.Nínú ìfúntí wáìnì rẹ̀ Olúwa tẹ́àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Júdà.

16. “Ìdí nìyí tí mo fi ń sunkúntí omijé sì ń dà lójú mi,Olùtùnú àti ẹni tí ó le mú ọkàn mi sọjí jìnnà sími,kò sí ẹni tí yóò dá ẹ̀mí mi padà.Àwọn ọmọ mi di aláìnínítorí ọ̀ta ti borí.”

17. Ṣíónì na ọwọ́ jáde,ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún un. Olúwa ti pàṣẹ fún Jákọ́bùpé àwọn ará ilé rẹ̀ di ọ̀ta fún unJérúsálẹ́mù ti diohun aláìmọ́ láàrin wọn.

Ẹkún Jeremáyà 1