Ẹkún Jeremáyà 1:18-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. “Olóòtítọ́ ni Olúwa,ṣùgbọ́n mo ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀.Ẹ gbọ́, gbogbo ènìyàn;ẹ wò mí wò ìyà mi.Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mini a ti kó lọ sí ìgbèékùn.

19. “Mo pe àwọn ọ̀rẹ́ miṣùgbọ́n wọ́n tàn mí.Àwọn olórí àlùfáà àti àgbààgbà miṣègbé sínú ìlúnígbà tí wọ́n ń wá oúnjẹtí yóò mú wọn wà láàyè.

20. “Olúwa, wòó, bí mo ti wà nínú ìnira!Tí mo sì ń jẹ̀rora nínú mi,ìdààmú dé bá ọkàn minítorí pé a ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi gidigidi.Ní gbangba ni idà ń parun;ikú wà nínú ilé pẹ̀lú.

21. “Àwọn ènìyàn ti gbọ́ ìrora mi,ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún mi.Àwọn ọ̀tá mi ti gbọ́ ìparun mi;wọ́n yọ̀ sí ohun tí o ṣe.Kí o mú ọjọ́ tí o ti kéde,kí wọ́n le dàbí tèmi.

22. “Jẹ́ kí ìwà ìkà wọn wá síwájú rẹ;jẹ wọ́n níyàbí o se jẹ mí níyànítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi.Ìrora mi pọ̀ọkàn mi sì káàárẹ̀.”

Ẹkún Jeremáyà 1